in

Oro olorun

*ẸKỌ KERINLELOGOTA (64):* *JÉSÙ KỌNI LẸKỌ LÓRÍ ÌFẸ GÉGÉBÍ ÒFIN TÌ O GA JULO* (26/05/24)

 *BIBELI KIKA:* MARKU 12:28-34.

 *a. Ilepa Eko:* Lati fi koni pe ki a fe Olorun ati aladugbo wa se iyebiye ju ebo sisun ati sise irubo lo.

 *b. Ese Akosori:* “Ife ki ise ohun buburu si ọmọnikeji re: Nitori na ife ni akoja ofin” Rom ;13:10.

 *c. Àwon Orin Ti O Ba Ẹkọ Mú:* Orin Ìhìnrere Akokun. 301.

 *d. Alaye Lori Eko*

 *i.* Mk 12: 28 Enikan ti a ko mo oruko re, sugbon ti o je oluko 0 sese pe o tẹti sile gbo àríyànjiyàn ti ở waiye larin Jesu ar:in ti Farisi.

 *ii.* Dajudaju ona ti Jesu gba dahun awon ibere ti a fi siwaju Rẹ te lọrùn, eyi wa mu ki o bere ibere tire pelu. O fe lati mo eyi ti tobi ju ninu gbogbo ofin.

 *iii.* Mk 12:29-30 Jesu tokasi Deut 6:5 wipe fife Olorun pelu gbogbo

 okan pelu aiya, ati iye ati gbogbo agbara ni akoko ninu o ofin.

 *iv.* Ninu Mk 12:31 Jesu Kristi ko akowe na pe fiferan aladugbo eni gege bi ara eni ni ofin keji ti o se pataki julo lehin ofin ki a fo Olorun.

 *v.* Mk 12:32-33 Akowe yi wa gba pelu Jesu Kristi pe titele awon ofin meji wonyi se pataki o si tayo gbogbo sise awon ise esin miran lo.

 *vi.*  Nitori pe oye ye akowe na o si tun se oloto, eyi mu ki Jesu ki o ehe e le ori osunwon pe ko jina si ijoba Olorun.

 *vii.* Mk 12:34 Nigbati Jesu ri i pe akowe na dahun pelu ogbon, Jesu gbe le ori osunwon pe ko jina si ijoba Olorun.

 *viii.* Bi o tile je wipe okunrin yi fihan pe on ni 0ye ti o jinle si awon ojuse ninu esin, sibe ko tii wole sinu ohun ijinle ti ijoba orun, nitori oye ti o ni je ipele ti imo ode ara. Sibe o nilo lati jowo aiye re fun Oluwa (Jesu Kristi).

 *ix.* Marku se akosile ninu ila ti o gbehin pe, eyi ni igba ikehinti awon alatako Jesu yo gbiyanju ati tun ma bi I ni ibere.

 *x.* Gege bi onigbagbo ninu Kristi, o ye wa ninu eko yi pe awon ofin Olorun ko ni inira ninu. A le mu won wale si ori awon ipele ilana meji wonyi nipa, ki o feran Olorun re ati ki o feran awon elomiran

 Deut 6:5; Lef 19:18. Wonyi ni imuse awon ofin Majemu Lailai.

 *xi.* A ko mo boya akowe yi pada wa di ọmọ-ẹhin Jesu lehin isele yi Igbala ko le duro lori ogbon ori nikan. Sugbon alaigbagbo gbodo koko ronupiwada, ki o tele Jesu. ki Emi Mimo so o di eda titun ati ki o si maa maa dagba soke nipa gbigbo oro Olorun.

 *xii.* A ko gbodo duro lori pe enia ko jina si ijoba Olorun ki a si jeki ey nikan te wa lorun. Dipo bee, seni o ve ki a gbe igbese ki a si maa gbe ninu ijoba naa.

 *e. Awon Ibere Idiwon Ara Eni*

 1. Nje o le feran aladugbo re lai feran Olorun bi? 2. Nje o le feran Olorun lai feran re aladugbo bi?

 _#TACNBA_

 _#ILEEKOOJOISIMI_

What do you think?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

GIPHY App Key not set. Please check settings

    Happy new month

    Happy new month to you all