in

Ko si ebo fun ese mo

Kàlẹndà Bíbélì fún Ọjọ Keje Oṣù Kẹwa, Ọdún 2024.

2 Ọba 6: 24-7: 20

Jeremáyà 37

Hébérù 10: 19-39

1. Ọlọ́run Síṣeéṣe

2. Ìsọsẹwọn Wòlíì

3. Kòsí Ẹbọ Fún Ẹṣẹ Mọ

1.  ỌLỌ́RUN SÍṢEÉṢE

Ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún Ọlọ́run láti ṣe; àwọn tí kò mọ̀ ọ́n yóò jìyà fún dídi agbára Rẹ̀ kù nítorí pé ó lè ṣe ohun gbogbo tí ó ṣèlérí láti ṣe, ó sì lè lo ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun láti mú ètò Rẹ̀ ṣẹ. Ó jẹ ohun ìjìnlẹ láti ríi pé àwọn Adẹtẹ mẹrin náà ni a lò láti lé gbogbo àwọn ọmọ ogun Orilẹ-èdè Síríà lọ ní ìṣẹjú kan láìsí wíwá òkodoro, àwọn ti wọn ti yí Samáríà ká fún ọpọlọpọ oṣù, àwọn tí ó ti fa ìyàn gidigidi ni Samáríà dé ibi tí àwọn ènìyàn n pa àwọn ọmọ wọn fún oúnjẹ. A lé àwọn ọmọ ogun náà lọ pẹ̀lú ìró Sẹkẹṣẹkẹ tí wọ́n gbọ́ bí wọ́n ṣe ń rò ó fún Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin Ogun àwọn ará Íjíbítì.  Ẹ jẹ́ ká fojú inú wo ìró tí wọ́n gbọ́, ó jẹ ẹ̀wọ̀n tí a so mọ́ ẹsẹ̀ àwọn adẹ́tẹ̀ náà kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ nípa ìrìn àjò wọn nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀ lójú ọ̀nà, kí wọ́n lè má bá àwọn ènìyàn pàdé torí pé àrùn ẹ̀tẹ̀ jẹ́ àrùn tó ń ràn mọ́ ènìyàn, àmọ́ Ọlọ́run dún ìró ẹ̀wọ̀n náà tí àwọn ọmọ ogun Síríà sì rò pé Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin Ogun Íjíbítì ni wọ́n, wọ́n sì sá lọ. Ọlọ́run máa ń lo àwọn aláìlera láti yọ àwọn alágbára lẹ́nu, yóò sì tún ṣe irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ ní Orílẹ-ède ̀wa láti lé àwọn ènìyàn búburú tí ń yọ Orílẹ-ède yìí lẹ́nu lọ. Ṣùgbọ́n èyí kò ṣẹlẹ̀ títí di ìgbà ìkéde Wòlíì Èlíṣà, ẹni tí ó sọ pé, “Ní wòyí ọ́la, wọn yóò ta ìwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára ní Ṣékélì kan.” A nílò láti fa ọwọ Ọlọ́run sọkalẹ nínú àwọn àdúrà pé kí ìròyìn ayò wà nínú ìgboro orilẹ-ede wa, ìròyìn rere ti ọpọ yanturu àti àlàáfíà, ìròyìn rere ti òmìnira àti ìfaradà ẹ̀sìn, ìròyìn rere ti òpin sí ìṣọtẹ àti ìsekúpani ní orúkọ Jésù.

2. ÌSỌSẸWỌN WÒLÍÌ

Àwọn Wòlíì tòótọ́ n bá ìṣòro pàdé nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn; a lè rántí bí Jeremáyà ṣe fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré nítorí ohun búburú tí àwọn ènìyàn ń ṣe fún un. Síbẹ síbẹ o kọ lati yẹsẹ, èyí tí ó fa ìfisẹwọn rẹ. Ṣùgbọ́n ọpọlọpọ àwọn wòlíì gbọjẹgẹ nítorí ìdúnkookò-mọni; àwọn kan n sọ ohun tí àwọn ènìyàn fẹ́ gbọ́, àmọ́ Jeremáyà, bó tilẹ̀ ti wà lẹ́wọ̀n n nì, tẹsíwájú láti sọ inú Ọlọ́run. Ohun yówù kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa lè jẹ́, a ó halẹ̀ mọ́ wa, ṣùgbọ́n a kò nílò láti gbọjẹgẹ tàbí yẹsẹ nítorí Jésù sọ pé, “A kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù àwọn tí ó lè pa ara, sùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí.” Gęgę bí Jeremáyà ṣe gba ìtura látọ̀dọ̀ Ọba, Ọlọ́run yó rán ìtura sí áwọn tó kọ̀ láti gbọjẹgẹ níbi tí wọ́n kò ti retí rárá. Àwọn ènìyàn Ayé nífẹ̀ẹ́ àwọn tí ń sọ irọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n ní ìkóríta kan, òtítọ́ yóò borí, wọn yóò sì wá àwọn olótìítọ́ kàn, gẹ́gẹ́ bí a ti pè Jeremáyà, ti a sì bèèrè pé bóyá àwọn ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Báyi ni ó se yẹ láti dúró ní ìhà Olúwa, ní sísọ òtítọ́ nígbà gbogbo.

3. KÒSÍ ẸBỌ MỌ FÚN ẸṢẸ

Ẹ̀ṣẹ̀ àmọọ́nmọ̀dá ni a o ṣèdájọ́ wọn níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé, pàápàá àwọn tí a ti yà sí mímọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn; a ó fìyà jẹ wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn lórí ilẹ̀ ayé kí a má bàa fìyà jẹ wọ́n ní Ọ̀run pẹ̀lú Ayé. Òǹkọ̀wé Èpístélì Hébérù tọ́ka sí i pé àwọn tí a ti sọ di mímọ́ gbọ́dọ̀ tiraka láti pa ara wọn mọ́ ní mímọ́ títí dé òpin ìgbésí ayé wọn. Gẹgẹ bí Ìwé Mímọ ti sọ, iṣẹ ìkẹhìn ni yó pinnu ìdájọ, bóyá búburú tàbí rere. Nítorí náà, a kò gbọ́dọ̀ fà sẹ́yìn, nítorí Ọlọ́run kórìíra ìpẹ̀hìndà, kòsì sí ìrúbọ mọ́ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ṣẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fọ̀ wá mọ́; nítorí náà, a gbọ́dọ̀ pa ìjẹ́mímọ́ wa mọ́ nínú Rẹ̀. Mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run mú wa dúró títí dé òpin ní orúkọ Jésù.

Olùsóàgùtàn M. O. Shodipe.

Fún Ìbéèrè: 08056044717

What do you think?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

GIPHY App Key not set. Please check settings

    Impossible prayer I

    God of possibilities