in

Sunday school

*EKO KERIN DIN LAADORIN ( 66 ) :* *JESU KILO FUN AWON TI NGBO ORO*

 *RE LATI SORA FUN AGABAGEBE AWON AKOWE*(09/06/2024)

 *BIBELI KIKA :* MARKU 12 : 38-40.

 *a .  Ilepa Eko :* Lati fi koni pe , awon agabagebe ninu ijo ni a o da lejo.

 *b .  Ese Akosori :* ” Nitoripe ajo awon agabagebe yíò tuka , ina ni yíò si jo ago abẹtẹlẹ ” Jobu 15:34.

 *c .  Awon Orin Ti O Ba Eko Mu :* Orin Ihinrere . 412

 *d .  Alaye Lori Eko*

 *i .*  Bi Jesu se nkoni leko lo sibe ninu Tempili , O ni ki won sora lodo awon akowe , o si so awon idi mefa ti nwon fi nilati sora fun won ( ese 38 ) .

 *ii .*  Idi akoko ni pe awon akowe fe máà lo kakiri ninu aso gigun . Ninu Num 15 : 37-40 , Oluwa pa a lase fun awon omo Israeli lati se waja waja si eti aso won ; idi ti o fi fi ase yi fun won ni ki won ki o ba le ma rántí awon ofin Oluwa . Sugbon awon akowe a ma se waja waja tiwon ki o tobi ju eyiti awon enia yoku nwo lo , boya lati fihan pe awon gbagbo ju awon enia ti o ku lo .

 *iii .*  Iwa buburu miran ti o wa ni owo awon akowe wonyi ni pe nwon feran ìkíni ni ibi oja . Oro yi ” Ìkíni ” ti a lo Nihin yii ga ju bibu ola funni ti a nfi fun awon ti o wa ni ipo giga tabi awon enia pataki ni awujo , Nihin yí fun awon akowe ( tabi awon oluko ofin ) . Wo Lk 11:43 pelu .

 *iv .*  Nwon a ma fe ijoko ola ninu Sinagogu . Ijoko yi tokasi awon ijoko ti o duro fun awon ijoko pataki ti a nto si owo iwaju ninu Sinagogu ti o si nkoju si awon ero inu ijo . O sese ki o je wipe ijoko yi ni a fun Jesu laye lati joko si ninu Lk 4:20 ..

 *v.* Ikerin , Mk 12:39 ; awon akowe wonyi a tun máa fe ibi aye giga ni ibi ase . Eyi ni ibi ti a ti pase sile fun awon eni pataki ni ibi ase . Jesu ba awon Farisi wí ninu Lk 11:43 nitoripe nwon a máa fe awon ijoko ibi giga ni ibi ase .

 *vi .*  Mk 12:39 ; Ohun miran ni jije ile awon opo run . Awon akowe ni oluko ninu ofin . Nwon ki igba owo fun ise ti nwon nṣe ; nitorina ohunkohun ti awon enia ba fun won ni nwon nlo tabi lati le máa fi se itoju ara won .

 *vii.* Opo ninu awon akowe wonyi a máà lo anfani yi lati re awon opo ti nṣe itoju nwon je .

 *viii.* Bi a se ntesiwaju ninu Mk 12 : 41-44 a o ri bi awon miran ninu awon opo wonyi se nfi irele ati otito inu josin si Olorun .

 *ix.* Ikefa Mk 12:40 Awon akowe wonyi a fe lati máa gbàdúrà gigun fun asehan . A ko gbodo si oro yi tumo si pe Jesu tako gbigba adura gigun patapata . Sebi On pelu gba adura fun ogoji osan ati ogoji oru Matt 4 : 2 . O si tun lo si ori oke lo igbadura ni gbogbo oru Lk 6:12 . Sugbon ni pataki julo O lodi si adura ti o nise pelu agabagebe

 *x.* Ni mimu idanileko na wa si idanuduro , Jesu Kristi Oluwa so ninu ese 40 pe awon akowe wonyi ni yíò jẹbi ti o po julo . Eyi ni nipe , a o fi iya nla je won nitori awon iwa agabagebe won .

 *xi .*  A ri ninu eko yi bi Jesu se tu awon akowe wonyi sita ti o si k’iwa nilo nitori iwa aimo ati agabagebe won .

 *xii .*  Gegebi Kristieni , kika Bibeli , gbigbadura ati aawe , ti o nṣàn idamewa ati ore , ti o si tun nṣe awon ojuse gbogbo miran ninu ijo , gbogbo nkan wonyi ni yíò bo si isin asan ati itanje bi iru eni bee ba nṣe e fun karimi ati iyin .

 *xiii .*  Bakanna , ihinrere wa gbodo ba awon ohun ti a gbagbo mu , ki a si máa gbe igbe aiye wa fun Kristi bi enikeni ko tile ri waa tabi bi a ko tile mo wa .

 *e .  Awon Ibere Idiwon Ara Eni*

1 .  Bi o ti wa ni igba ti Jesu Kristi , nje o ro pe agabagebe wa ninu ijo loni bi ?

2 .  Kini o ro pe a le se lati mu iwa eeri ati agabagebe kuro larin ijo loni ?

 _#tacnba_

 _#Ilé-èkóỌjọ́-isimi_

What do you think?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

GIPHY App Key not set. Please check settings

    No matter how long have you slept … You always want those 5 MINUTES in the Morning.

    Morning greetings doesn’t only mean saying Good Morning, it has a silent message saying: I remember you when I wake up!